AWON EBUN IFIHAN
A. ORO IMO
Bob Whitaker ti fi awon oro wonyi sapejuwe ebun yi “ki i se nipa oye imo eko; o je imo ati-‘nu-wa iru eyi ti a ri ninu ise-iranse Jesu nigbati o mo ohun ti awon alatako Re n ro tabi ti won n pete, ti o si fun won lesi bi eni pe o mo ohun ti o wa lokan won” (Mk. 2:8, Lk 6:8, 7:36-47; 9:47). Oro Giriki ti a fi se apejuwe ebun yi tumo “mimo kan jinle”. O ni lati ye w ape iru imo yi ki i se nkan kan na pelu ifihan to yato nipa Bibeli. Ebun yi ko wa fun ete ati fi kun iwe-mimo. O je ifihan otito nipa awon isele, awon eniyan tabi nkan eyi to je atorunwa, to yato, to tayo iseda, ti o si wa lati odo Emi-Mimo, eyi ti oye eran-ara ko le mo loju lasan. E je ka sayewo awon ese Bibeli wonyi lati mo ebun yi si: Gen 2:21-23, Acts 5:1-4, Lk 4:17-19, 2Kgs 5:20-27, 2 Kg 6:32-33, Jn 4:17-18.
Okan lara awon ogbun ti o ye ka kiyesi gegebi eni to ri ebun yi gba ni otito pe o seese fun wa lati bere si i se gaaru nitori awon iwoye ati ise-iranse ti a fihan. Ewu miran tun ni jije ise to ye ka je ni koro ni gbangba. Awon miran tile le gun igi rekoja ewe nipa fifunni ni ayederu oro imo nigbati ifihan Kankan ko tile wa.
B. ORO OGBON
Eyi je akanse agbara ti Emi fifunni lati ri isele ati oro lati agbon ti Olorun ki a si fi iwoye Olorun dahun si gbogbo agbon aini.
Genesis 41 fun wa ni apeere ifarahan ebun yi. Ninu ise-iranse Jesu, oro ogbon jeyo ninu bi o se fun awon to fe ko ba lesi (Matt. 21:23-27; 22:23-33, Lk 20:20-26). Eni to ba ri ebun yi gba yio le lo imo tie mi lona to moju. A ri apeere ebun yi miran ninu ona ti Solomoni gba yanju ija to suyo laarin awon obinrin meji lori omo to wa laaye. Awon to ba ni ebun yi a maa se dada gege bi omo iko to n gbani nimoran. Won si le ran ijo lowo lati la akoko rogbodiyan ja.
Awon ewu to wa ninu lilo ebun yi nip e o seese fun eni to ni ebun yii lati jo ara re loju, ko bere si i ro ara re ju bi o se ye ni riro lo tabi ki o ma le ni suuru pelu awon ti ko ba teti si oro re.
C. MIMO EMI YATO
Eyi je akanse agbara Emi lati mo iyato laarin awon emi. Lona miran ewe, o je agbara lati mo boya oro kan , ise tabi erongba kan ti odo Olorun wa, tabi o je tie ran ara ese abi o se wa lati odo esu. E je ka wo awon ibi-kika yi ninu iwe mimo lati ni oye to ye kooro nipa bi ebun yi se n sise: Matt 16:23, Acts 8:9-25; 16:16-18, I Tim 4:1, 2Pet 2:1-2, 1Thess 5:21.
Okan lara awon adimeru aleebu ebun yi nip e o seese fun eniti o n lo lati ma a fi iwanwara dode eko-eke, o kan le ma a bu enu ate lu gbogbo nkan tabi ki o ma fa seyin lati ijo kan si omiran.
AWON EBUN AGBARA
A. EBUN IGBAGBO 1 COR 12:9
Ebun igbagbo ni akoko ni isori awon ebun agbara o si je opo mulero ninu eka yi. Ebun igbagbo ki i se nkankan na pelu igbagbo ti o n mu igbala wa eyi ti gbogbo Kristiani ni (Rom3:22; 5:1). O je akanse agbara Emi lati mo daju wipe Olorun fe se ohun kan o si daju pe yio se. Lede kukuru, o je mimo ohun ti Olorun fe se ati nini igboya wipe yio se. E je ka sakiyesi ifarahan ebun yi ninu iwe mimo: Gen 22:8, Jn 11:23, Matt 14:29, Acts 27:21-26. Ewu kan to wa pelu awon to n lo ebun yi nip e o seese fun won lati lo ebun naa laini ife (1Cor 13:2) tabi ki won ma ni suuru pelu awon ti won ma n sora ju.
B. AWON EBUN IMULARADA
O je akanse ebun ti Emi Mimo funni lati je ohun elo ti o n mu imularada ti ara, ti okan ati ti emi wa lona to yato. Nkan to ye ka fun ni akiyesi Pataki nipa ebun yi ni oro isodopo ti a lo, eyi toka si awon oniruiru agbara to ni i se pelu orisirisi arun, majemu titun fun wa ni ona meji din logoji ti Jesu ti se iwosan si ri ona metadinlogun ti Paul ati awon miran ti se iwosan ninu Ise awon Aposteli. Yi je aparutu fun enikeni lati fenu oro jona pe ko si ebun yi mo. E je ka wo inu iwe mimo: Ex 15:26; 23:25, Ps 103:3, Matt 6:56, Acts 10:38, Heb 2:4, 2Kg 20:1-7, 1Tim 5:23, Jn 14:11-14.
Awon aleebu eniti o n lo ebun yi niwonyi:
· Gbigbiyanju lati wonisan nigbakugba laiwoye idari Emi
· Lilo awon ona ti iwe mimo ko fidi won mule
· Mimu ki imularada da lori igbagbo alaisan na
· Sise aimusuuru nigbatiiwosan ko ba tete sele
C. SISE AWON ISE IYANU – 1 COR 12:10
Eyi ni afihan agbara atorunwa ti o tayo, eyi ti o doju ofin iseda bole lati se afihan agbara ati iwalaaye Olorun ninu eto aye omo eniyan. A si wa ninu igba ise iyanu, opolopo awon eniyan si wa lokunrin lobinrin ti a fi ebun ifihan agbara Olorun yi fun. Awon ese Bibeli wonyi jeri si ifarahan ebun yi. Ise 13:8-11, 2:22, Mk 6:2; Lk 10:13, Gal 3:5, 2Kor 12:12, Matt 12:28, Jn 2:1-10 Mk 4:35-41, 5:21-43, Lk 7:11-17, Jn 14:12-14, Heb 2:3-4. Lile awon emi esu jade wa lara awon ise ebun yi.
Aleebu ti eniti o ba ni ebun yi le ni ni pe o seese ki o ma sise laisi idari Emi ki o si ma gba ogo to ye ko je tOlorun.
AWON EBUN ORO SISO
A. EBUN ISOTELE 1 COR 12, 1 THESS 5:20, MATT 7:15-16
Eyi je akanse ebun ti Emi fi funni lati gba ise-iranse lati odo Olorun ki a si je ise na lati fe imo awon onigbagbo loju, ki a gba won niyanju ki a si mu nkan da won loju 1 Kor 14:3-5. Isotele ni i se pelu ifihan ati oro siso. Oro Giriki ti a lo fun isotele tumo si pe “ki a fohun jade”. O ni iha ki a “so nkan sita” ati “ ki a so nkan tele”. Ise 11:27-28;21:10-11; 13:1-3, 1 Tim 1:18, Ifihan 1:3, Rom 12:8. Isotele wa ni abala meta “imuduro”, “igbaniyanju” ati “itunu” (igbaninimoran) 1 Kor 14:3,9. Wipe o ni ebun isotele ko tumo sip e woli ni o. awon ogbun ti o ye ki a kiyesi niwonyi:
· Igberaga
· Yiyago kuro ninu iwe mimo
· Siso oro sakasaka tabi jije ise iranse laifi ogbon kun
A gbodo dan gbogbo isotele wo loju ina oro Olorun Deut 18:20-22.
B. AWON ONIRURU EDE
Ebun yi dabi eyi ti o ni ariyanjiyan ju ninu gbogbo awon ebun Emi. Ti a ko ba fi ebun yi si ibi ti o ye, o le da rukerudo ati iyapa sile. Lede kukuru, a le so pe o je akanse agbara ti Emi fifunni lati soro ni ede ti eniti o n lo ko mo tele ti ko si ko ri. E sakiyesi oro isodopo ti a lo fun ni 1 Kor 12. E je ka kiyesi awon nkan wonyi lati inu ibi kika yi:
· Ogofa awon onigbagbo fi ede fo lojo Pentecost. Ise 1:15; 2:4.
· Idile Koneliu lehin ti won dahun si iwasu Peteru Ise 10:46
· Apejo awon onigbagbo Efesu kan Ise 19:6
· Paulu papa fede fo 1 Kor 14:5, 18
· A ni “ede” ti o je pe Olorun nikan soso la fi n ba ni gbolohun (aladani)
· O ni “ede” ti o wa fun ise-iranse si awon eniyan. Eyi ni a menuba ni 1 Kor 12 (awujo) se ayewo 1 Kor 14 finnifinni.
· Kiyesi ede “eniyan” tabi ti “awon angeli” ninu 1 Kor 13.
Eniti o ba ni ebun yi ni lati kiyesi awon nkan wonyi:
· Lilo ebun na laisi ife
· Fifi ede se gbedeke fun idagba temi
· Lilo ebun na fun ogo ara eni
C. ITUMO AWON EDE 1KOR 12:10
Eyi ni akanse agbara Emi lati tumo ise ti a je ninu ifedefo si ede to yeni. Itumo yi le wa lati odo eniti o n fede fo (1 Kor 14:5, 13) tabi lati odo elomiran (1 Kor14:27). Nigbati itumo ba wa, ifede fo na ko ni gbe eniti o fede fo nikan ro, sugbon yo gbe gbogbo eniti o wa nibe ro pelu. Itumo na le ma je oro kookan sugbon yi o funni ni koko ise iranse na. Nigbati a ba ti tumo ede, a ma jamo isotele. Ogbun ti o ka yago fun ni jije ise ti ki i se Emi Mimo lo ran ni, gbigba ogo fun ifarahan ebun na tabi riro pe a dara ju awon ti ko ni ebun yi lo.
AWON EBUN ASOMOGBE
A. ISAKOSO/IDARI 1 KOR 12:28, ROM 12:8
Ebun yi ni i se pelu akanse agbara nipa isakoso eyi ti o n ran eniti o ni ebun yi lowo lati dari agbo Olorun si ibi ise won yi o ti muna doko. Oro Giriki ti a tumo isakoso ni 1 Kor 12:28 tumo si “eni ti o n to ni sona tabi ti o n dari eni sipa afojusun kan”. Nipa agbara idari, eniti o n lo ebun yi a ma yan awon ilepa/afojusun, a si ma seto bi awon ilepa na yi o se kesejari nipa agbara isakoso. Sayewo awon ese Bibeli wonyi: 1 Thess 5:12, 1 Tim 5:17, 1Pet 5:2-3, 1 Tim 4:14, Heb 13:7, 17:24. Eniti o ba n lo ebun yi ni lati kiyesara ko ma ma “lo” awon eniyan tabi ki o ma’ wa won pa’ nipa rironu ise ati eto ju awon eniyan lo.
B. IGBANINIYANJU/IGBANI NIMORAN (ROM 12:8)
Eyi ni agbara ti Emi funni lati se i gbaniniyanju to muna doko, ki a tuni ninu, ki a runisoke tabi ki a baa won miran yi lati ran won lowo lati gbe igbe aye ti o wu Olorun. Oro Giriki “parakaleo” ti a tumo si igbaniniyanju ninu Rom 12:8 n toka si “diduro ti elomiran lati gbaniyanju, gbero tabi tu u ninu ki a sit un ru soke, ro o tabi bawi nigbati o ba ye, fun idagba temi ati lati ru ara wa soke si ife ati ise rere (Heb10:24). Fun oye si, sayewo Ise 14:21-22, 4:36; 11:25-26; 13:5; 15:37-39; Lk 22:32; 2 Tim 4:2 ati Jn 14:16
Ewu ti o le dojuko eniti o n lo ebun yi niwonyi:
· O le je ki awon eniyan dara de e ju nipa kiki orun bo aye won ju
· O le se aibikita nipa igbe-aye emi re ni pa pe o fe ran awon miran lowo.
C. EBUN IFIFUNNI (ROM 12:8)
Eyi ni fifi ara eni tabi ohun ini eni jin fun ise Oluwa. Oro Giriki ti a lo ni Rom 12:8 se atenumo “fifunni tabi pipin ara wa” bi a se n se ififunni. A ri apeere eyi ninu Bibeli ninu igbe aye obinrin opo (Lk21:1-3), ati Dokasi (Ise 9:36-39) 1 Thess 2:8
Awon aleebu re niwonyi
· Gbigberaga nipa ififunni
· Dida awon ti ko le fifunni pelu isera-eni lebi
· Bibu enu ate lu bi awon miran se n nawo won
D. ISALEJO
Oore-ofe ti Emi fun ni lati feran, ki ni kaabo, ki a si salejo pelu oyaya tobe ti awon alejo na ko fi ni mala pea won ko si nile 1Pet 4:9-10, Acts 16:15, 1 Tim 3:2; 5:10, 3Jn5:8,Rom 16:23. Ewu ti o wa ninu lilo ebun yi ni ki eniti o ni ebun yi ma je ki awon eniyan ma sadeede lo nilo omi ojo, ati ko ma le so pe rara nigbati o ba ye.
E. FIFI AANU HAN (ROM12:8)
Agbara lati fi oro ro ara eni wo ki a si ni ikaanu fun awon ti o wa ninu isoro ki a wa fi i si oju ise nipa fifi tayo tayo se ise sin elomiran. Awon ewu ibe niwonyi:
· Kikaanu ju bo ti ye lo laifi ogbon se
· Riraga boa won ti a n toju ju bi o ti ye lo
· Jije ki bi nkan na se ri lara wa ma dari wa ju otito ati oro inu iwe mimo lo
Iha wo lo ye ka ko si lilo ebun yi? Rom 12:8
Se ayewo ilo ebun yi lati inu Lk 4-8. Ki la ri ko lati inu Ise 9:36 ati Jn 2:15-16, Matt 25:35-45.
Lati owo Alufa Dele Kolade
Mo dupe fun iwulo ati amulo idanileko yi ni ede abinibi wa. Mo nlo lati fi ko awon elomiran.
ReplyDelete